"O sọ fun mi pe ti mo ba gbiyanju lati salọ, oun ma pami."
Pascaline, 22, ranti ọrọ ọkunrin to fi ipabalopọ ninu ọgba ẹwọn Goma, ilu to tobi ju lorilẹede Congo ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kinni.
"Mo ni tiraka lati jẹ ko ṣeeṣe ki ma ba padanu ẹmi mi," Pascaline sọ fun BBC.
Oun ni ọkunrin keji ti yoo fipa balopọ ninu ọgba ẹwọn Munzenze ree. O daku lasiko ti akọkọ waye.
Awọn eeyan to n kọlu yii wa lati ọdọ awọn ọkunrin, to wa ni ẹgbẹ keji, ti wọn sọ "Safina", o ṣalaye.
"A gbọ ariwo bi wọn se n fo ferese omi. Wọn pọ, ti ẹru si n ba wa. Awọn ti ori ko koyọ ni wọn fipa ba lopọ, ti awọn ori ba se si jade lai ni ibalopọ.
Rogbodiyan bẹ silẹ ninu ọgba ẹwọn naa ati ayika rẹ. Awọn ọmọ Rwanda n sumọ Goma.
Ọpọ awọn wọda ọgba ẹwọn lo ṣalọ , ti awọn alaṣẹ naa ko gbẹyin. Wọn n gburo ibọn ni ita ọgba ẹwọn
Lẹyin ọpọ wakati, ninu agbaala, ina n jo, ti awọn ọkunrin to wa ni ọgba ẹwọn da silẹ bi wọn se n gbiyanju lati salọ.
Nigba to ma fi di owurọ, o le ni ẹgbẹrun mẹrin ọkunrin to ti salọ. Ṣugbọn awọn obinrin diẹ ko gbẹyin. Ni apapọ, obinrin 132 ati ọmọ mẹdọgbọn lo jona, gẹgẹ oṣojumikoro meji ṣe sọ.
Oṣiṣẹ ajọ agbaye UN sọ fun BBC pe o le ni 153 to padanu ẹmi wọn.
Lẹyin oṣu kan, Pascaline pada si ibi to ti bajẹ ni ọgba ẹwọn.
O sọ itan rẹ, to si gba lati fi oju rẹ han. Bakan naa lo tun sọrọ fun awọn oku.
O rin kaakiri, to si n wo ayika.
"Nigba to di asiko kan, n ko mọ nnkan to nsẹlẹ mọ," o sọ . "Nigba ti mo ri pe awọn yooku n ku, ni mo bẹrẹ si so ara jọ. Mo ma ni Ọlọrun ma la mi."
Alubọsa ni Pascaline n ta, ko to di pe o ba ara rẹ ni ọgba ẹwọn nigba ọga rẹ ni ibi iṣẹ fẹsun kan pe o jale.
Nadine, 22, naa pada wa si ọgba ẹwọn fun igba akọkọ. Ninu ọkan rẹ, ko le salọ.
"Ti mo ba sun lalẹ, gbogbo nnkan to wa ni ibi bayi ni yoo pada wa. Mo n ri oku- ju eyi ti mo ri ki n to jade . Wọn kọ lati si ilẹkun, wọn fi wa silẹ ka ku bi ẹranko ni ibi bayii."
Nadine ni ọkunrin meji naa lo ba opun lọpo
"Wọn wa pẹlu ọti," O sọ fun BBC. "Wọn fẹ fun awọn eeyan ni oogun oloro, wọn fi tipatipa mu mu. Wọn mu gbogbo obinrin ni bi bayii.
BBC ko le fi idi iye obinrin ti wọn ba sun ni alẹ ọjọ naa mulẹ ninu gbogbo awọn obinrin 167.
Nadine n binu si awọn alaṣẹ fun bi wọn ṣe ti mọle ni akọkọ lori igbese to jẹ.
"N ko ro pe idajọ ododo wa ni Congo, mo bu ẹnu atẹlu awọn ijọba to n da ri nnkan."
Ijọba, ti olu ilu wa ni Kinshasa ko da nnkankan mọ ni agbegbe Goma. Awọn agbebọn yii ni dari agbegbe, ti wọn si ti n murile guusu.
Awọn obinrin to wa ni ọgba ẹwọn ni wọn fun ni anfani lati mu awọn ọmọ wa pẹlu wọn. Ọmọ meji nikan lori koyọ ninu ijamba ina naa.
Florence, 38 naa ṣalaye, o ni "awọn ọmọ n ku" nigba ti wọn yin tajutaju si ọdọ awọn obinrin.
"Awọn ologun wa ni ayika ọgba ẹwọn, to yẹ ki wọn wa gba wa silẹ ki wọn pa ina, wọn kan yin tajutaju si wa ni," Florence ṣalaye.
Ajọ kan to n ja fun ẹtọ ọmọniyan ni fifi ipa ba eeyabn lopọ wa laarin irinsẹ ogun lati ọwọ awọn agbebọn yiii ati awọn ijọba.
"Awọn eeyan n ku niwaju mi, n ko le ka wọn. A gbiyanju pe ka fun wọn ni ọmọ. Oorun naa mu ti awọn kan ko si le mi daada," Florence sọ fun BBC.
Florence ni bi awọn eeyan ku ko sẹyin kudiẹkudiẹ ijọba.
O yẹ ki wọn si ilẹkun nigba ti wọn ina .
"A kan si ijọba ni Kinsasha fun esi si awọn ẹsun wọnyi ṣugbọn a ko ti gba esi pada.
Florence ni ago mọkanla ni wọn si ilẹkun ọdọ awọn obionrin, to si jẹ pe oun pẹlu eeyan mejidinlogun lo ri aye lati bọ sita
Ni ile Iwosan Goma, a ba obinrin ti ori ko yọ, Sifa, 25, to ni oun yọ ọrẹ oun kan ninu ina.
O fi ẹgbẹ kan sun nitori ẹgbẹ keji n dun. Wọn ba fi n we ọwọ rẹ keji.
Ọmọ rẹ, Esther, ọmọ ọdun meji ku lasiko ikọlu naa.
"Mo gbe Esther si ẹyin mi. Nigba ti a fẹ salọ, nnkan ja lu. Ado oloro? N ko mọ. O ku lẹsẹkẹsẹ," Sifa sọ fun BBC.
O fikun Esther ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni ma rin, ti ko si ni ẹsẹ ni ọrun rẹ. Nigba mii o ma n ba awọn ọmọ yooku sere ninu ọgba ẹwọn ṣugbọn ni gbogbo ọdọmiay rẹ lo ma n wa ju.
Bawo ni Sifa se dero ọgba ẹwọn, wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu idigunjalẹ, eyi to ni oun ko mọ wọ.
O wa lẹwọn lai foju ba ileeẹjọ. Awọn eeyan ilu naa ni ki se tuntun.
Ohun to sẹlẹ ni ọgba ẹwọn Munzenze ni o ṣe ko ma ri ita. O da bi pe awọn to wa ni agbara ko ti ṣetan lati mọ.
Sifa ati awọn yooku ti ori ko yọ ni ko ti si ẹnikẹni to wa ba awọn sọrọ nipa ohun to sẹlẹ ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kinni.
Comments
Leave a Comment