Lẹyin nnkan bii ẹgbẹrun ọdun meji gbako ti ọkunrin kan ku ninu ina fokano, awọn onimọ ijinlẹ ti ṣawari pe ọpọlọ rẹ ti di gilaasi ninu eeru gbigbona ina ọhun.
Ọdun 2020 lawọn onimọ ijinlẹ ri gilaasi naa ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe ọpọlọ ti o di gilaasi ni amọ wọn ko mọ bo ṣe ṣẹlẹ.
Inu agbari oloogbe naa ni wọn ti ri gilaasi ọhun ti iwọn rẹ tobi bii eso.
Iwadii fi han pe ẹni ogun ọdun ni oloogbe naa lasiko to ku lọdun 79AD niluu kan lagbagbe ilu ti a mọ si Naples, lorilẹede Italy lonii.
Gẹgẹ bi awọn onimọ sayẹnsi ṣe sọ, eeru gbigbo to korajọ lo jo ọpọlọ naa titi to fi di gilaasi.
Wọn ni ọpọlọ ọhun ni akọkọ iru rẹ ti ẹya ara eeyan yoo di gilaasi funra rẹ.
Ọjọgbọn Guido Giordano lati ile ẹkọ Università Roma Tre, sọ fun BBC pe "ohun ti a ṣawari yii jẹ ohun ara meeriri."
Ọkunrin kan to ku lori ibusun rẹ lẹba ile kan ti wọn n pe ni Collegium to wa ni adugbo Herculaneum lo ni ọpọlọ ọhun.
Iwọn gilaasi ti wọn ri ni ọpọlọ rẹ jẹ iwọn sẹntimita kan si meji, ti awọn kan si jẹ iwọn milimita.
Lọdun naa lọhun, ina fokano naa gba Herculaneum, eyii to wa lẹgbẹ ilu Pompeii ti nnkan bii ẹgbẹrun lọna ogun eeyan gbe.
Lonii, awọn onimọ sayẹnsi gbagbọ pe Vesuvius ni eeru gbigbona naa ti kọkọ wa, eyii to fa iku ọpọ eeyan nibẹ.
Lẹyin naa ni eeru mii ti wọn n pe ni 'pyroclastic' tun tẹle.
Wọn ni ọpọlọ oloogbe naa ti gbọdọ gbona de iwọn 510C ko to bẹrẹ si n tutu, eyi to mu ko di gilaasi.
Yatọ si ọpọlọ naa, ko si ẹya ara rẹ mii to tun di gilaasi mọ.
Comments
Leave a Comment