Ọpọ eeyan lo si n rọ ero wọn lori iwe ti olori orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ajagun fẹyinti Ibrahim Babangida kọ nipa ara rẹ to pe akọle rẹ ni "Irinajo lẹnu iṣẹ" (A journey in Service) eyi to ṣe ifilọlẹ rẹ laipẹ yii.
Lara awọn alẹnulọrọ to ti sọ ero wọn nipa iwe naa ni agbẹjọro agba ati ajafẹtọọ ọmọniyan, Femi Falana (SAN).
Amofin agba Falana ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch idi to fi fẹ gbe Babangida lọ ile ẹjọ.
Lakọkọ, Falana sọ pe Babangida, Ọgagun fẹyinti Muhammadu Buhari, Ọgagun fẹyinti Sani Abacha atawọn ologun mii gbimọ pọ lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kejila ọdun 1983 lati gbajọba alagbada labẹ alaṣẹ Aarẹ Shehu Shagari.
Falana ni Babangida funra rẹ ditẹ gbajọba lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 1985 ti o si kede ara rẹ gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria.
''Fun ọdun mẹjọ gbako ni Babangida fi ba ọrọ aje Naijiria jẹ pẹlu oniruuru eto ti ko kẹsẹjari bii Structural Adjustment Programme (SAP) ti ajọ IMF ni ko ṣe agbekalẹ rẹ.
Ijọba Babangida ju ọpọ ọmọ Naijiria si atimọle lọna aitọ, ọpọ ajafẹtọọ ni ijọba rẹ gbe lọ sile ẹjọ tawọn ologun si ṣekupa awọn eeyan kan tori wọn tako ijọba ologun to wa lode,'' Falana ṣalaye.
Ẹri to daju wa pe ijọba Babangida ko jẹ ki iwadii iku Dele Giwa kẹsẹjari - Falana
Gbajugbaja agbẹjọro naa tun sọ pe Babangida fagile eto lati da ijọba pada fun alagbada ni igba mẹrin ọtọtọ pẹlu agbekalẹ ofin ologun nọmba 25 to ṣe lọdun 1987.
O ni Babangida fofin de awọn oloṣelu, o si tun wọgile esi ibo abẹnu awọn ẹgbẹ oṣleu.
Falana sọ pe pabanbari rẹ ni pe Babangida tun fagile esi ibo aarẹ ''June 12'' ọdun 1993 eyi ti MKO Abiola jawe olubori ninu rẹ.
Agbẹjọro agba naa sọ pe Babangida tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ni oniruuru ọna lasiko ijọba rẹ.
Falana ni ọpọ awọn agbẹjọro ajafẹtọọ mii lo ti pinnu lati ṣatilẹyin foun lati igba toun ti kede pe oun yoo gbe IBB lọ ile ẹjọ.
Bakan naa ni o sọ pe ajọ to n ri aabo ẹtọ ọmọniyan ti kede wi pe awọn yoo ṣe akojọpọ awọn eeyan ti Babangida ti ẹtọ ọmọniyan wọn mọlẹ fun ẹri nile ẹjọ.
''Ijọba Babangida ṣekupa Ọgagun Mamman Vatsa atawọn ọgagun mii pẹlu ofin ologun iditẹgbajọba ti Babangida ṣe lẹyin ti wọn mu awọn ọgagun naa lori ẹsun iditẹgbajọba.
Lasiko Babangida naa ni wọn fi lẹta to ni ado oloro ninu pa gbajugbaja oniroyin, Dele Giwa,'' Falana lo sọ bẹẹ.
Falana ni ile ẹjọ ajọ ECOWAS ti sọ pe orilẹede to ba kọ lati ṣe iwadii ipaniyan ọmọ ilu rẹ lọwọ ninu iṣekupani ọhun.
Agbẹjọro agba naa sọ pe ẹri to daju wa lati fidi rẹ mulẹ pe ijọba Babangida ko jẹ ki iwadii iku Dele Giwa kẹsẹjari.
O ni ijọba IBB tun dina mọ oloogbe agbaọjẹ agbẹjọro n ni, Gani Fawehinmi (SAN) lati gbe awọn afurasi to ṣekepa Dele Giwa lọ ile ẹjọ.
Comments
Leave a Comment