"Lẹyin ti mo da obitibiti owo ti wọn gbagbe sinu ọkọ mi pada fawọn ọlọpaa, mi o le rin lọja, lẹnu iṣẹ tori iha awọn araalu to gbọ nipa ohun ti mo ẹ".
Ni ọdun 1971 lọhun lọhun ni iṣẹlẹ yii waye amọ nibayii, o dabii pe itan Shonubi Mohibi ti re oko igbagbe ti ko si si ẹni kankan to ranti ati dupẹ tabi mọ riri ore ti Ayodele Muibi Shonubi.
Muhibi ṣalaye iru idẹyẹsi to foju ri latọdọ awọn alabaṣiṣẹ rẹ gẹgẹ bi awakọ.
"Gowon lowa nijọba nigba naa lọhun lọdun 1971, àwọn ti mo gbe ọhun ni awọn ṣata ọkọ mi ni mo dẹ ni ko buru, maa gba pọun mẹẹdogun wọn si fara mọ ọ, wọn tun ra epo fun mi.
O ṣalaye pe lẹyin ti oun gbe awọn to wọ ọkọ ohun de ibi ti wọn n lọ ni awọn ọmọ to fẹ ba a fọ ọkọ sare wa sọ fun un pe baagi kan wa ninu ọkọ rẹ.
"Kete ti mo ṣi baagi ti mo ri i pe owo lo kun ibẹ ni mo ni ki wọn pa mọto de ti mo si gbe owo naa lọ agọ ọlọpa".
Ki lo wa ṣẹlẹ lẹyin to da owo pada?
Alagba Muibi ṣalaye pe nigba ti yoo fi di ọjọ keji ti ọrọ naa ti bọ sori iroyin kaakiri pe "ọgbẹni Muibi kan ri owo olowo he o si ti gbe e wa fun ijọba, Muibi ko jẹ egun mọ iyan".
"Ki ni mo ṣe tan, nigba ti maa fi de gareeji ti mo ti n wa ọkọ lọjọ keji, ṣe ni wọn n pariwo le mi lori ti orukọ mi di Muibi Arowomagbe e.
Iyawo Mubi naa sọ iriri rẹ ni ọja tori pe o n duna dura ọja kan ti wọn si gbe ọrọ rẹ hanu ti wọn n muu bu pe ko ṣe ni na ọja ni inakuna nigba to jẹ pe "Arowoma gbe e loun ati ọkọ rẹ pe akuṣẹ lasan lasan ti ko le la laye ni wọn.
Comments
Leave a Comment