Ẹmi sun, ọpọ dukia si ṣofo nibi ijamba ọkọ to sẹlẹ ni opopona mọrosẹ Oko-Olowo si Jebba ni ilu Ilorin, nipinlẹ Kwara.
Ileeṣẹ panpana ipinlẹ Kwara fidi rẹ mulẹ pe eeyan kan lo ku ninu ijamba ọkọ tirela kan to ko ajilẹ ati tanka agbepo ti wọn kọlu ara wọn ni opopona mọrosẹ Oko-Olowo si Jebba ti ina si ṣẹyọ lọjọ Ẹti ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji ọdun yii.
Ileesẹ panapana ipinlẹ ṣalaye ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Ileesẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, fi lede pe iwadii fi han pe tirela to ko ajilẹ naa lo fẹ ya tanka epo ọhun lati ẹyin sugbọn ti o kọ lu u lẹgbẹ.
Ọgbẹni Adekunle ni lẹyin naa ni epo inu tanka ọhun danu ti o si gbina.
Agbẹnusọ naa fikun ọrọ rẹ pe isẹlẹ yii lo ṣokufa bi awakọ tirela naa se ha sinu ọkọ, to si jona sibẹ.
Ọga agba Ileesẹ panapana ipinlẹ Kwara, Ọmọba Falade John Olumuyiwa, ti wa rọ gbogbo awakọ ati awọn to n lo oju popo lati maa ṣe suuru loju ọna, ki wọn si maa tẹle ofin irinna lati dena irufẹ isẹlẹ bayii lọjọ iwaju.
Nigba ti BBC Yoruba de ibi isẹlẹ naa, egungun ori ati ẹsẹ eeyan nikan ni a ri to n jona ti awọn ẹya ara iyoku si ti jo di eeru.
Gẹgẹ bi a se gbọ lẹnu awọn ti isẹlẹ naa ṣoju wọn, nkan bi ago mẹjọ abọ owurọ ọjọ Ẹti ni ijamba naa ṣẹlẹ ti ina si bẹẹrẹ sii jo fun bii wakati meji.
A tun rii wi pe ko si ọkọ kankan ti o le kọja nibi isẹlẹ naa ki wọn ma baa fara kaasa ijamba ina.
Ni se ni awọn ọkọ to lọ rẹrẹ ni apa ọtun ati apa osi, ko si si ẹnikan to le sun mọ ibi isẹlẹ naa.
Lẹyin o rẹyin, awọn panapana de ni nkan bi ago mẹwa abọ lẹyin ti ina ti n jo fun bii wakati meji.
Bi ijamba naa ṣe waye
Ọkan lara awọn ti isẹlẹ naa soju rẹ, Ọgbẹni Sheu Arọbadi, sọ wi pe ọkọ tirela to ko ajilẹ lo fẹ yaa tanka agbepo sugbọn ti o kọlu u ti ina si ṣẹyọ lati ibẹ.
Arọbadi sọ pe bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ ni awọn eeyan to wa lori ọkọ tirela naa bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn.
"Awọn ero to wa lori awọn ajilẹ ninu tirela naa n fo bọ silẹ ni ọkọọkan, awọn kan da lapa, bẹẹ si ni awọn kan da lẹsẹ.
"Koda baba ati ọmọ wa ninu wọn ti a si ri baba naa to kọkọ ju ọmọ rẹ silẹ lati ori ọkọ naa ko to di pe oun paapaa bẹ silẹ.
"Gbogbo awọn ti o farapa ni wọn gbe digba lọ ile iwosan fun itọju.
"Sugbọn a o mọ iye eeyan ti wọn wa ninu awọn ọkọ yii, igba ti a sun mọ ibẹ ni a ri awọn egungun ori ati ẹsẹ.
"Gbogbo awọn ẹya ara iyoku ti jo di eeru, ko si si aye fun ẹnikẹni lati da eyan kan mọ ninu awọn to jona yii,'' Arobadi ṣalaye.
Ọgbẹni Arọbadi ni agbegbe naa ni oun n gbe pe ko si ọsẹ kan ti ijamba ọkọ ko ni pa awọn eeyan ni opopona mọrosẹ naa.
O rọ ijọba lati daasi ọrọ ona naa ki wọn si fi opin si ohun to lee maa fa ijamba ọkọ ni gbogbo igba.
Ni iwoye tiẹ, afara ni ọna naa nilo pe ti ijọba apapọ ba le mu ni baada lati kọ afara sibẹ, ijamba ọkọ yoo dinku.
Comments
Leave a Comment