Lọdọọdun ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn musulumi maa n gba awẹ fun ọgbọnjọ lasiko Ramadan.
Fun bii ọdun meloo bayii ni awẹ Ramadan ti bọ si asiko ooru lapa ariwa ile aye ti awọn orilẹede bii Amẹrika, Canada, India, China ati ọpọ orilẹede Asia wa.
Amọ, lọdun yii asiko otutu ni awẹ Ramadan bọ si pẹlu asiko ti wọn ri oṣu lati bẹrẹ awẹ.
Eyi tumọ si pe ilẹ kii tete mọ lawọn orilẹede kan si awọn miran.
Iru ipa wo ni eyi le ni lori agọ ara rẹ?
Ohun to n ṣẹlẹ ninu ara rẹ nigba ti o ba ṣẹṣẹ bẹrẹ awẹ
O maa n to wakati mẹjọ ki ara eeyan to faye gba awẹ gbigba lẹyin ti ẹni naa ko ba jẹun fun igba kan.
Asiko yii ni onlọ inu ti lọ ounjẹ ti eeyan jẹ kẹyin tan ti awọn mudun-mudun lati inu ounjẹ si n ṣara loore.
Lẹyin naa ni agọ ara yoo ṣamulọ ṣuga lati inu ẹdọ ati iṣan lati pese agbara fun eeyan.
Ti ara ba ti lo ṣuga lati inu ẹdọ tan, ọra ni yoo tun maa pese agbara fun eeyan.
Ti ọra inu ara ba ti bẹrẹ si ni yọ ni eeyan yoo bẹrẹ si ni ru diẹ diẹ, eyi yoo si ṣe iranwọ fun agọ ara lati ma le ni arun itọ ṣuga.
Amọ, adinku ṣuga ninu ẹjẹ yoo maa jẹ ki o rẹ eeyan.
Eeyan tun le maa ni ẹfọri tabi ki ooyi maa kọ eeyan pẹlu.
Asiko yii gan an ni ebi maa n pa eeyan gan an.
Ṣọra fun omi amuju ni ọjọ kẹta si ọjọ keje awẹ
Bi o ba ti bẹrẹ si ni gba awẹ ni ọra ara yoo maa yọ ti yoo si maa di ṣuga ninu ẹjẹ.
Omi mimu to ti dinku ninu awẹ yoo jẹ ki oungbẹ maa gbẹ eeyan.
O yẹ ki ounjẹ ti o n jẹ lasiko awẹ ni ohun elo aṣaraloore ati ọra ninu.
O tun ṣe pataki lati jẹ ounjẹ to ni ohun elo aṣaraloore pẹlu iyọ, ki eeyan si maa mu omi daadaa.
Awẹ ti n ba ara mu lati ọjọ kẹjọ si ikẹẹdogun
Ipele kẹta niyii, lasiko yii ni awẹ yoo ti maa ba agọ ara mu daadaa.
Dokita Razeen Mahroof ti ile iwosan Addenbrooke ni Cambridge sọ pe awọn anfaani mii tun wa ninu gbigba awẹ.
Dokita Mahroof ni ''lasiko ti ko si awẹ, oriṣiiriṣii ounjẹ to maa n jẹ ki eeyan tobi leeyan maa n jẹ.
Gbogbo eyi lo maa n ni atunṣe lasiko awẹ, awẹ gbigba maa n jẹ agọ ara ṣiṣẹ daadaa.
Awẹ gbigba maa n jẹ ki ara ni laafia, o si maa n gbogun ti arun tabi aisan ninu agọ ara.''
Lati ọjọ kẹrindinlogun si ọgbọnjọ awọ
Awẹ yoo ti mọ eeyan lara daadaa laarin ọjọ kẹẹdogun akọkọ.
Lẹyin naa, ẹya ara bii ẹdọ, kindinrin ati awọ ara yoo mọ toni toni.
Dokita Mahroof fikun ọrọ rẹ pe ''lasiko yii ninu awẹ, gbogbo ẹya ara ni yoo ti maa ṣiṣẹ daadaa.
Eeyan yoo le ronu daadaa, yoo si tun lagbara si.
Ko yẹ ki ara maa lo eroja inu ounjẹ aṣaraloore fun agbara, eyi maa n ṣẹlẹ lasiko ti eeyan ba n gba awẹ ti agọ ara si maa n lo iṣan fun agbara.
Bi a ti n gba awẹ lati idaji si irọlẹ, o yẹ ki a maa jẹ ounjẹ to ni eroja aṣaraloore ninu ki a si maa mu omi daadaa.''
Njẹ awẹ gbigba dara fun ilera ara?
Dokita Mahroof ṣalaye pe awẹ gbigba dara fun agọ ara tori o maa n jẹ ki eeyan mojuto ounjẹ ti eeyan n jẹ.
Dokita Mahroof ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awẹ gbigba fun oṣu kan dara, ṣugbọn o le mu ewu dani ti eeyan ba n gba awẹ ni gbogbo igba.
Dokita naa ni awẹ gbigba kii ṣe ọna to dara to lati din ara sinsin ku tori agọ ara ko ni le sọ ọra inu ara di agbara mọ.
O ni eyi ko dara fun agọ ara tori ai jẹun fun igba pipẹ le ṣakoba fun ara.
Dokita Mahroof ni eeyan le maa gbaawẹ lẹkọọkan lẹyin Ramadan, amọ, ko dara fun agọ ara lati maa gbaawẹ fun ọpọ oṣu lera lera.
Comments
Leave a Comment